About Us

Yobamoodua.org jẹ́ ibi ìpamọ́ orí ẹ̀rọ ayélujára fún àwọn ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìperí oríṣiríṣi ní èdèe Yorùbá tí a gbé kalẹ̀ láti kọ́ afárá gba oríi kùdìẹ̀kudiẹ tí ó ń kojú àìpọ̀ tó ohun èlò orí ayélujára ní èdèe Yorùbá àti lóríi to bridge the ẹ̀rọ ayárabíàṣá gbogbo. Ibùdó yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìràpadà tí Yobamoodua Cultural Heritage ti gbé ṣe. YMCH bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìgbélárugẹ lábẹ́ẹ Yobamoodua ní ọdún-un 2012 nípasẹ̀ pínpín àwọn ìtàn ìbílẹ̀ àti nǹkan ọrọ̀ tí ó jẹ́ àmúyangàn ìran Yorùbá, bíi ìṣe, àṣà tòun iṣẹ́ ọnàa wa pàápàá lórí gbàgede ìkẹ́gbẹ́ ti ẹ̀rọ ayélukára bí ajere. Ọdún-un 2017 ni a forúkọsílẹ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tí ó ń ṣàkóso ètò okoòwò ní Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi iléeṣẹ́ apèsè ìròyìn, YMCH ti ṣe ọ̀kan-ò-jọ̀kan àyànṣe iṣẹ́ sẹ́yìn. YMCH ń ṣe àkóso ètò ìpolówó ọjà, ògbufọ̀ àti ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdèe Yorùbá advertising copy writing àti láti Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì. Ní abẹ́ ìṣàkóso Adéṣínà Ayẹni tí àwọn ènìyán mọ̀ sí Ọmọ Yoòbá, Yobamoodua ti ṣètò ìpolówó ọjà fún iléeṣẹ́ OANDO, Interswitch One Africa Music Fest, ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè fún ibùdó ìtakùn indigenous tweets, Engine Room, Localization Lab, Global Voices àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Báwo ni ibùdó yìí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?                                  
Kò sí àní àní, bí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, oníṣẹ́ ohun èlò orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá tàbí No matter who you are, olùkọ́ni, Yobamoodua.org ni ibùsọ̀ fún èdèe Yorùbá, ìwúrí àṣà àti ìṣe tí ó ní kìmín nínú; ibi ìṣúra fún àwọn nǹkan àjogúnbá ilẹ̀ẹ Yorùbá. YMCH ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí fínnífínní, àgbékalẹ̀ mọ̀ ọ́ kọ mọ̀ ọ́ kà èdè, àpérò nípa èdè àti ìtúmọ̀ fún àṣàrò láàárín ọ̀jẹ̀ onímọ̀ nípa èdè, akẹ́kọ̀ọ́ èdè àti akọ̀ròyin àti àwọn ògbóntarigì nínú ètò ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ láti forí korí fún àtúnṣe sí gbólóhùn àtijọ́, hun ọ̀rọ̀ tuntun yálà fún ìmọ̀ ẹ̀dá abẹ̀mí, ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá àti onírúurú ìmọ̀ tí ẹ̀dá mọ̀. Ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì nítorí ayé ń yí bíríbírí lọ́nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí, ìmọ̀ ẹ̀rọ ti sọ ìgbà dọ̀tun, ó sì yẹ kí àwa náà ó bá ayé yí, ó yẹ kí á ní ọ̀rọ̀ ìperí fún ohun gbogbo tí ó ń bẹ ní orílẹ̀ alààyè ní èdèe Yorùbá, láti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sí ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ìgbésẹ̀ ńlá yìí ni láti mú ìdàgbàsókè bá èdèe Yorùbá kí ó ba máà di ohun ìgbàgbé àti èdè àtijọ́ àmọ́ láti gbé e sóríi àwòrán ilé ayé níbi tí àwọn èdè ìgbàlódé-lonígbà-ń-lò wà.

Láfikún, ibùdó yìí wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá, àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè ìdánwò WAEC, NECO, àti JAMB láti ọdún-un 2012 wà fún ìpalẹ̀mọ́ ìdánwò tí ó ń bọ̀ lọ́nà.

Yobamoodua.org is an online repository of words and terminologies in the Yorùbá language developed to bridge the digital divide and marginalization of the Yorùbá language on the internet and on all digital platforms. This site is an offshoot of the numerous revival efforts by Yobamoodua Cultural Heritage. YMCH began Yobamoodua in 2012 with the dissemination of information about the Yorùbá cultural tradition and arts on the internet using social media as a media and offline through storytelling. Officially registered as an information service business in 2017, YMCH has undertaken numerous projects. Amongst other services offered by YMCH include advertising copy writing and production, translation services from English language to Yorùbá language and vise versa. Under the coordination of Adéṣínà Ayẹni otherwise known as Ọmọ Yoòbá, Yobamoodua had produced advertisements for brands like OANDO, Interswitch One Africa Music Fest, worked on a number of translation projects like the indigenous tweets website, Engine Room digital projects, Localization Lab, Global Voices and many more.

How can this site help you?
No matter who you are, or what you do, be you a student, developer or teacher, Yobamoodua.org is your one stop Yorùbá language, cultural values and traditions website; a database for general information about the Yorùbá cultural heritage. YMCH conduct research, organizes language classes, host translation sprint event whereby linguistics, students, journalists and other professionals in the education and tech industry converged to create new or modify old terms; words; nomenclature whether in biology, history and what have you from all works of life. This step is necessary because the world is moving at a very fast pace in technological advances and we should follow trends, we need to have words for everything in the world in the Yorùbá language, from tech to science. This feat is to develop the Yorùbá language for it not to go into extinction and also to place it on the world map as a modern language and not primitive.

In addition, this site is useful for Yorùbá students, there are WAEC, NECO and JAMB past questions and answers from 2012 to study to prepare you for your next examination.

Want to support the project?

Click here!

Our Team
Ọmọ Yoòbá – Administrator

Anthony Edung Toju – Web Design Manager

Ọpẹ́yẹmí Aleem – Marketing Executive