ÀYÍPADÀ OJÚ-ỌJỌ́

ÌMỌ̀Ọ́ D’ÒYE: A Literacy Resource on Climate Change for Non-English Speakers of Yorùbá Origin

Ète Ẹ̀kọ́


Ìfojúsùn ẹ̀kọ́ yìí ni láti mú èdèe Yorùbá gbòòrò sí i kí ó ba figagbaga pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè àgbáyé àti láti kéde ìṣòro Àyípadà Ojú-ọjọ́ fún àwọn ọmọ Káàárọ̀-o-ò-jí-ire tí kò gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì. Bákan náà ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè ìperí tí à ń lò ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò láti inú èdèe Gẹ̀ẹ́sì, torí ìdí èyí ni a ṣe ní láti hun ọ̀rọ̀ tuntun tí kò sí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́rí, iṣẹ́ àkànṣe yìí ń mú àbá náà ṣe nípasẹ̀ híhun èdè ìperí fún Àyípadà Ojú-ọjọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí-ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ni ó yànàná ohun kan tàbí òmíràn nípa àyípadà ojú-ọjọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí à ń pè ní Àyípadà Ojú-ọjọ́, àfọwọ́fà ẹ̀dá ọmọ ènìyàn àti ipa ìṣẹ̀lẹ̀ àdámọdá tí ó lọ́wọ́ sí ìṣòro àyípadà ojú-ọjọ́, títí kan àwọn ọ̀nà ìgbé ilé ayé tuntun. Ní ìtẹ̀síwájú àlàyé, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí-ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ló ní àwòrán-àtohùn oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún tí òmíràn kò sì tó bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwòrán àti àtẹ-àwòràn-àtọ̀rọ̀. Ìbéèrè wà ní àárín àwọn àlàyé pẹ̀lú ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè ní ìparí ẹ̀kọ́. Ṣíra tẹ ibí kí o gba ẹ̀dà àkànṣe-iṣẹ́ náà sílẹ̀.

Aim(s) of the resource
The aim(s) of the resource is to grow the Yorùbá language as well as create awareness on the global climate change crisis for non-English speakers of Yorùbá origin. Also, most of the words we use are borrowed from English and we need to create words for the things we hitherto have no term for, this resource is an attempt to coin new words in relation to Climate Change. Each of the topics are combination of two or more topics under climate change. Starting with the explanation of what is meant by Climate Change, the human and natural drivers of Climate Change, to Climate Change adaptation procedures. For further exploration, each of the related issues are presented in audio-visual format of 5 minutes duration or less and also images/infographics. There are intermittent questions and answers at the end of the resource to test the comprehension of the user. Click here to download the content of the project.

Ẹ̀kọ́ yìí (gba ẹ̀dà rẹ̀ sílẹ̀) wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìmúró àfojúsùn ìdàgbàsókè 4: tí ó ń lépa ìkàkún gbogbo ènìyàn àti ètò ẹ̀kọ́ tó yè koro àti ìmọ̀ ayérayé.
_________________________________
This resource (download) is linked to Sustainable development goal 4: Ensure inclusive and quality education for all and promote lifelong learning.  

Nípa Ibùdó Ẹ̀kọ́ náà

Ibùdó yìí jẹ́ ilé ìṣúra àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ “èdè abínibí”, ó sì ní àlàálẹ̀ fún àwọn tí ó bá fẹ́ fi ara tọrẹ fún iṣẹ́ ọ̀fẹ́.

Kíni Àyípadà Ojú-ọjọ́?

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó ń ṣe ìwádìí sí àyípadà ojú-ọjọ́ ti ṣàkíyèsí wí pé àwọn àyípadà oníṣísẹ̀ntẹ̀lé ti ó ti ń ṣẹlẹ̀ ní lemọ́lemọ́ ní bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn jẹ́ àrídájú t’ó yanrantí. Èdè ìperí Àyípadà Ojú-ọjọ́ lágbàáyé ni a fi ń ṣe àpèjúwe ìyàtọ̀ tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí ojú-ọjọ́ lágbàáyé, tí ó ń ṣe àfikún àlékún ìwọ̀n-ìgbóná-àti-òtútù, látàrí àpọ̀jù èéfín nínú àyíká.

Ìyàtọ̀ bíntín wà láàárín ojú-ọjọ́ àti ìgbà ojú-ọjọ́ (afẹ́fẹ́ ilẹ̀ ibì kan tàbí ti ìlú kan) àmọ́ èyí kò fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn èèyàn. Ìgbà ojú-ọjọ́ ni ojú-ọjọ́ ìgbà pípẹ́ èyí tí ó jẹ́ pé a lè ṣe àfọ̀tẹ́lẹ̀ bí ojú-ọjọ́ agbègbè kan yóò ṣe rí ní àkókò kan. Èyí kọ́ ni yóò tọ́ka iye òjò tí yóò rọ̀ ní ọjọ́ kan tàbí bí ìwọ̀n-òtútù yóò ṣe rí ní ọjọ́ kan. Ojú-ọjọ́ ní tiẹ̀ ni bí àyíká yóò ṣe rí fún ìgbà díẹ̀. Ọjọ́ méjì ni a leè fi sọ bí ojú-ọjọ́ yóò ṣe rí. Ìwòye ojú-ọjọ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ ṣe é ṣe àmọ́ kò ṣe é gbọ́kànlé. Ìyẹn ni pé ó ṣòro láti sọ bí afẹ́fẹ́ ilẹ̀ ọjọ́ kan yóò ṣe rí. A leè sọ pé afẹ́fẹ́ ilẹ̀ tàbí ti ìlú kan ni “àpapọ̀ agbede” ojú-ọjọ́. Ọ̀nà mẹ́ta ni a lè gbà ṣe àgbéyẹ̀wò nípa ojú-ọjọ́:

 • Àyípadà ojú-ọjọ́ sáà yìí àti sáà tí ó kọjá
 • Okùnfà àyípadà ojú-ọjọ́ sáà yìí àti sáà tí ó kọjá
 • Àbájáde àyípadà ojú-ọjọ́ ìgbàanì àti òní

Ẹ̀rí tí ó dájú nípa Àyípadà Ojú-ọjọ́

Níwọ̀n ìgbà tí kò ti ṣe é ṣe kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ó ṣe ìrìn-àjò padà sí ayé àtijọ́ láti mọ bí afẹ́fẹ́ ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i àpapọ̀ ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru àti bí òjó ṣe rọ̀ sí ní ìgbà náà, ohun tí ó kù wọ́n kù láti ṣe ni kí wọn ó ṣe àyẹ̀wò sí òṣùwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru. Láti ṣe èyí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sinmi lé ẹ̀rí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá nípa afẹ́fẹ́ ilẹ̀ ayé ní ìgbà àtijọ́.

Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìwádìí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, nǹkan àdánidá mẹ́ta lọ́wọ́ sí àyípadà ojú-ọjọ́ àgbáńláayé. Ìkìníní ni òbìrìkìtì Milankovitch. Òbìrìkìtì Milankovitch ṣe àpèjúwe ìyọrísí àyípadà ṣíún tí ó ṣẹlẹ̀ sí afẹ́fẹ́ ilẹ̀ Ilé-ayé níbi àyípo Ilé-ayé. Gígùn òbìrìkìtì Milankovitch náà máa ń wáyé ní àárín ọdún 19, 000 àti 100, 000. Ní ọ̀rọ̀ kan, ó fi hàn wí pé àsọtẹ́lẹ̀ àyípadà afẹ́fẹ́ ilẹ̀ Ilé-ayé tí ó ní ṣe pẹ̀lú àyípadà òbìrìkìtì ayé máa ń wáyé ní gbogbo 19, 000 ọdún.

Ìyàtọ̀ ìgbóná oòrùn ni nǹkan àdánidá kejì tí ó fa àyípadà ojú-ọjọ́. Ìtànṣán oòrùn ni iye agbára tí oòrùn ràn ní àkókò kan. Àjọṣepọ̀ wà láàárín ìgbóná oòrùn àti ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru. Bí ìgbóná ooru bá ṣe lọ sókè sí i (tàbí wálẹ̀ sí i), ni ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru Ilé-ayé náà yóò ṣe lọ sókè (tàbí wálẹ̀ sí i).

Ní àkótán, ìtújáde òkè-oníná-tíí-máa-rú-èéfín ni àdánidá tí ó ṣ’ìkẹ́ta nínú ohun tí ó ń fa àyípadà ojú-ọjọ́. Ìtújáde òkè-oníná-tí ń-rú-èéfín leè ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọjọ́ díẹ̀, àmọ́ àwọn nǹkan tí ó le àti afẹ́fẹ́ tí ó tu jade nígbà tí òkè-oníná náà ń rú èéfín leè mú àyípadà bá ojú-ọjọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún díẹ̀, tí yóò sì fa àyípadà ojú-ọjọ́ ìgbà díẹ̀. Àwọn afẹ́fẹ́ àti ohun tí ó le bí òkúta tí ó tujáde láti inú òkè-tí-ń-rú-èéfín yìí leè jẹ́ òyì-èédú, hydrogen sulfide, hydrogen àti èéfín. Ní àkópọ̀, ìtújáde òkè-oníná-tí-ń-rú-èéfín leè mú afẹ́fẹ́ tutù. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1783 nígbà tí àwọn òkè-oníná tí í-ṣe-èéfín ní orílẹ̀-èdèe Iceland tújáde tí ó sì fọ́n sulfuricoxide tí ó pọ̀ sí inú afẹ́fẹ́.

Àwọn nǹkan àdánidá mẹ́ta lọ́wọ́ sí àyípadà ojú-ọjọ́

Àwọn òyì inú àyíká gan-an ni ó ń ṣe bẹbẹlébẹbẹ ní ti ọ̀rọ̀ afẹ́fẹ́ ilẹ̀. Bí agbára ooru oòrùn bá ràn lé ilẹ̀-ayé, àwọn afẹ́fẹ́ kan yóò sé ooru yìí mọ́ inú àyíká, gẹ́gẹ́ bí àwọn jígí tí a fi yí ibi tí a fi ṣe ọ̀gbìn ká ṣe máa ń mú ooru sílẹ̀ pàápàá bí àyíká bá tutù. Àwọn òyì inú àyíká tí ó kóbá ilẹ̀-ayé ni òyì-èédú, methane, ooru omi, nitrous oxide, àti Òyì-àrá. Àwọn òyì inú àyíká máa ń fa ìtànṣán ó sì máa ń tu ìtànṣán jáde, bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ nǹkan pàtàkì tí ó ń fa ìbàjẹ́ inú àyíká: ìgbóná ilẹ̀-ayé látàrí òyì-èédú àti àwọn òyì inú àyíká mìíràn.

Wo àwòrán-àtohùn ráńpẹ́ yìí ní èdè Gẹ̀ẹ́si tí ó dá lé orí ipa òyì inú àyíká àti bí ó ti ṣe ń pa ilẹ̀-ayé.

Ẹ̀rí wà nípa àbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín àwọn òyì-èédú tí ó wà nínú àyíká àti ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru àyíká: bí òyì-èédú ṣe ń lọ sókè síi, ni ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru àgbáyé náà ń lọ sókè. Àpọ̀jù òyì-èédú inú àyíká ní sáà tí a wà yìí ti ju irú èyí tí a ti rí lọ – àyípadà náà lọ sókè ní àárín ọgọ́rùn-ún ọdún ju ti ẹgbẹ̀rúnlọ́nàẹgbẹ̀rún ọdún tí ó rékọjá lọ.

Àpọ̀jù òyì-èédú inú àyíká
Kí ni èrèdí ìyàtọ̀ tí ó wà ní àárín bí àyípadà ṣe ń ba nǹkan jẹ́ àti bí òyì-èédú ṣe ń pọ̀ sí i?    

Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì tí ó yẹ kí a mọ̀ bí a bá ń ṣe àfiwé àkọsílẹ̀ ìgbàanì àti ti sáà tí a wà yìí ni àfọwọ́fà àwùjọ ìgbàlódé; kò sí ohun tí ó mú àyípadà bá ojú-ọjọ́ ṣẹ̀ bíkòṣe ti àpọ̀jù òyì-èédú nínú àyíká. Wo ibi tí àwọn èéfin/ òyì-èédú in àyíká ń lọ níbí.

Ìṣe ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn fọ́n òyì-èédú àti methane, méjì nínú àwọn òyì tí ó jẹ́ kókó jù lọ nínú gbogbo òyì sí inú àyíká fún oríṣìíríṣìí ọ̀nà. Ohun tí ó tú òyì-èédú sínú àyíká jù lọ ni jíjó dànù àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ tí ó ń fa èéfín bíi epo rọ̀bì, afẹ́fẹ́ ìdáná, àti èédú. Bíbẹ́gilulẹ̀ láì gbin òmíràn rọ́pò, ìwa ẹfun-ilẹ̀ fún ìmọlé, iṣẹ́ àgbẹ̀ ẹran ọ̀sìn, oko pípa, àti igbó sísun jẹ́ díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ-ènìyàn tí ó fa àpọ̀jù òyì-èédú nínú àyíká.

Àwọn onímọ̀ ní ẹ̀rí àyípadà ojú-ọjọ́ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òde òní tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òkè-ńlá-omi-dídì tí ó ti ń ṣe wẹ́rẹ́ yinrin àti àwọn agbègbè omi dídì tí kò dáwọ́ yíyọ́ dúró tí ó sì ń fa àkúnya omi ọ̀sà káàkiri àgbáyé. Onírúurú nǹkan ló ń mú kí omi òkun ó máa kún ní àkúnya, ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru omi (ọwọ́ ìtutù tàbí ìmóoru omi ni yóò sọ bí omi yóò ti ṣe kún tó) ni yóò tọ́ka sí bí omi odò, adádò yóò ṣe tó, àti bí àwọn òkè-ńlá-omi-dídì, agbègbè omi dídì àti ìrì dídì orí òkun yóò ṣe yọ́. Bí àwọn òkè-ńlá-omi-dídì àti agbègbè omi dídì ṣe ń yinrin, ni omi yóò ṣe máa kún ní àkúnya.

Ní báyìí, àyípadà ojú-ọjọ́ leè ṣe àkóbá fún àwọn ẹ̀dá alààyè. Bákan náà ni ó ń kóbá àwọn ohun tí kì í ṣe ẹ̀dá-oníyè. Bí àyípadà ṣe ń bá afẹ́fẹ́ ilẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ni àyípadà ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru ti ń kóbá. Ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru àti òjò níṣẹ́ kọnta ní í ṣe ní ti ìṣètò ewéko, ẹranko àti àwọn àkókò inú ọdún agbègbè iléayé kan.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo sí ìṣòro ìgbóná àgbàńláayé tí ó ti ara àyípadà ojú-ọjọ́ súyọ ni ṣíṣe àtúntò àwọn ìlànà tí a fi ń ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀. Kí ìyàtọ̀ ó tó dé bá iléayé, a ní láti dín pantí àyíká kù, kí a rọra lo omi, kí a má lo agbára iná mọ̀nàmọ́ná lápọ̀jù, kí a máa gbinigi, kí a máa lo ohun èlò tàbí ẹ̀rọ tí kò lo epo rọ̀bì, àti ìdínkù èéfín nínú àyíká.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Kí ni ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín afẹ́fẹ́ ilẹ̀ àti ojú-ọjọ́?
 2. Èwo nínú àwọn ohun àdánidá wọ̀nyí ni ó lọ́wọ́ sí àpọ̀jù òyì-èédú àti àwọn òyì mìíràn nínú àyíká?
  A. Jíjó àwọn àlùmọ́ọ́nì abẹ́ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí epo, èédú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
  B. Àrànfẹjú ìtànṣán oòrùn
  D. Òkè-iná-tí-ó-ń-tú-èéfín-jáde
  E. Òbìrìkìtì Milankovitch
 3. Kí ni àwọn arapa àyípadà ojú-ọjọ́?
 4. Kí ni ó fa àyípadà ojú-ọjọ́?
 5. Kí ló dé tí omi òkun-ún fi ń kún àkúnya?
 6. Ọ̀nà wo ni àfọwọ́fà ṣe mú kí òyì-èédú ó pọ̀ nínú àyíká?

Àwọn arapa Àyípadà Ojú-ọjọ́

 • Omi mímọ́ ń tán lọ
Omi ti ń dín kù

Bí òkún bá ń kún ní àwọn agbègbè kan, omi odò àti adágún-odò ti ń gbẹ ní àwọn ibòmíràn lágbàáyé, wo àwòrán tí ó fi bí adágún-odò Chad ṣe ń gbẹ.

Bí a ṣe lè pọn omi òjò sílẹ̀ lọ́nà tí ó ní ìlera

Omi òjò gbígbè ni irúfẹ́ omi pípọn tí ó jẹ́ wípé a ó gbe omi òjò tí a ó sì pọn ọ́n sílẹ̀ de òǹgbẹ, ó sàn ju kía jẹ́ kí wọn ó jò dànù. A leè gba omi òjò ní odò tàbí láti ọ̀ṣọ̀rọ̀ òrùlé àti àtúndaríi rẹ̀ sínú ihò jíjìn (kọ̀nga, ikùdù, tàbí omi kangádẹ̀rọ), kùdù, omi àpọn sílẹ̀ tí a gbà sílẹ̀ láti ara ìrì, ìkùùkù pẹ̀lú àwọ̀n tàbí ohun èlò mìíràn. A máa ń lò ó fún ìpèsè omi ọgbà, omi ẹran-ọ̀sìn, bíbomirin, lílò nínú ilé, ìmúlémóoru, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó kù níbí.

 • Aburú tí ohun ọ̀gbìn tí a ti fi ọwọ́ pa kádàráa rẹ̀ dà (GMO) àti ajílẹ̀ ń fà fún ẹ̀dá alààyè gbogbo
Kòkòrò Tí ń jẹ ewé

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Kíló ń fà á tí omi adágún-odò Chad ṣe ń gbẹ?
 2. Ọ̀nà wo ni ọmọ-ènìyàn ń gbà rí omi lò?
 3. Dárúkọ ọ̀nà méjì tí a lè fi pọn omi sílẹ̀ de oǹgbẹ
 • Ìmúfọn òyì-àrá

Afẹ́fẹ́ ni òyì-àrá, irúfẹ́ òyì-iná kan ni. Bí kò bá sí òyì-àrá nínú ìpele ayé inú afẹ́fẹ́ ní ìta àgbáńlá ayé kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ohun abẹ̀mí tí ó tó bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

Ní àárín àwọn ọdún mẹ́wàá ti o wà nínú 1970 sí 1980, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ banújẹ́ wí pé tí ó bá máa fi di àádọ́ta ọdún ìpeleòyì-àrá lè ti fi ìdá 3 bùkù. Nígbàtí ó máa fi di ìparí ọdún mẹ́wàá tí ó wà láàárín 1980 sí 1990 ó ti ṣẹlẹ̀!

Ikú

Ìpolongo nípa ìtànṣán UV-B ti gbajúmọ̀ látàrí wí pé ó máa ń fa jẹjẹrẹ àwọ̀ ara; àtafọ́ ojú àti ojúfífọ́; pa ẹ̀dá àìfojúrí inú omiòkun, bí irú èyí tí ó sì ń mú ìdìnkú bá ẹja àti ìbùkù iṣẹ́ kọntakọnta tí àwọn ẹ̀dá àìfojúrí inú òkun tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìfàmu òyì-èédú inú afẹ́fẹ́ –tí àwọn ẹ̀dá àìfojúrí inú òkun ń ṣe ju igi lọ. UV-B ní ń mú kí ohun ọ̀gbìn ó má ta dáadáa, ó sì tún ń mú kí irè oko ó má pọ̀ jọjọ. Ọ̀dádá tí ó dá èyí sílẹ̀ ni CFC, tí kò lóòórùn, tí ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú èròjà oògùn apakòkòrò ń ṣe díẹ̀ nínú ìṣòro yìí. Bí a bá tiẹ̀ dín ìlò CFC kù lónìí, a ó ṣì rí arapa rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ó lé.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Báwo ni ìpele òyì-àrá ṣe ń dá ààbò bo ilẹ̀ ayé?
 2. Ọ̀nà wo ni àfọwọ́fà ṣe mú kí òyì-èédú ó ba òyì-àrá jẹ́?
 • Kòkòrò, oògùn apakòkòrò àti iṣẹ́ẹ láabi tí wọ́n ṣe láyé ẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn

Bí a bá fi àwọn oògùn apakòkòrò ṣe àkóso oko kí irúgbìn ó ba so dáadáa, ó máa ń lẹ́yìn. Ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbẹ̀ ò kíyèsí ni aburú tí oògùn wọ̀nyí ń kó bá ìlera ẹ̀dá orí ilẹ̀ gbogbo. Kò sí bí a ṣe se ẹ̀fọ́ ebòlò tí kò ní í rùn, kò sí bí a ti ṣe lè lo oògùn apakòkòrò kí ó má wọ inú àgọ́ ara, nítorí látara omi mímu àti oúnjẹ jíjẹ ni aṣaburú yìí ń bá bọ́ sínú àgọ̀ ara ẹ̀dá ọmọ ènìyàn àti ẹranko. Arapa oògùn apakòkòrò tí ó wọ inú àgọ́ ara wa ló ń ṣokùnfà àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan àrùn àti àìlera tí ń kojú ẹ̀dá alààyè. Àwọn àrùn bíi àìleèrọ́mọbí, jẹjẹrẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kò ṣẹ̀yìn-in àwọn apakòkòrò àtọwọ́dá tí a ń sọ wọ̀nyí.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Ní ọ̀nà wo ni oògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀ ṣe ń pa ilẹ̀?
 2. Ọ̀nà wo ni ọmọ-ènìyàn ń gbà kó àrùn láti ara oògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀?
 • Ìṣòro Ìpèsè Oúnjẹ Àgbáyé

Ilẹ̀ ọ̀gẹ́rẹ́ afọkọ́yẹrí amomisanra máa ń ṣá bí a bá lò ó lálòjù, tí ó fi jẹ́ wí pé ohunkóhun tí a bá gbìn sórí rẹ̀ kò ní ta dáadáa, bí ó bá sì ta, ó lè má so jìngbìnnì. Síbẹ̀, bí a bá fi ilẹ̀ oko náà sílẹ̀ fún bí ọdún méjì, yóò padà bọ̀ sípò, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ lode òní, nítorí àlòjù àti àpọ̀jù oògùn apakòkòrò, ajílẹ̀ àti àwọn ìlànà ìṣàgbẹ̀ ìgbàlódé.


Láì sí afẹ́fẹ́ ilẹ̀, iṣẹ́ àgbẹ̀ kò ní ṣe é ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ní sí ẹja lómi. Àpọ̀jù ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru àti èéfín leè mú kí àwọn ohun ọ̀gbìn agbègbè kan ó so jìngbìnnì. Àmọ́ kí èyí ó tó wáyé, àwọn èròjà tí ó tọ́, rínrin ilẹ̀, omi àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó ṣe gbòógì bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ wà. Ọ̀dá àti ọ̀gbàrá omi tí ó ń ṣe lemọ́lemọ́ leè fa ìpèníjà fún àwọn àgbẹ̀ arokobọ́dúndé àti àgbẹ̀ ẹlẹ́ranọ̀sìn tí ó sì lè fa ìfàsẹ́yìn fún ìpèsè oúnjẹ. Síbẹ̀, omi tí ó lọ́wọ́ọ́rọ́wọ́ lè mú kí àyípadà ó dé bá ilé ẹja àti ìṣesí ẹja. Gbogbo rẹ̀ jùlọ, àyípadà ojú-ọjọ́ lè mú un nira láti fọ́n irúgbìn, sin ẹranko, àti pa ẹja ní ọ̀nà tí a ti ń gbà ṣe é àti níbi tí a ti ń ṣe é tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́rí. Ó yẹ kí a tún wo àyípadà ojú-ọjọ́ láti ara àwọn ìlànà ìṣàgbẹ̀ òde òní àti ìlò ìmọ̀ ẹ̀rọ, nítorí àwọn liana tuntun wọ̀nyí ń lọ́wọ́ sí ohun jíjẹ.

Ó ṣe é ṣe kí àyípadà ojú-ọjọ́ ó kóbá ìpèsè oúnjẹ lágbàáyé, lágbègbè àti ní ìgbèríko. Àyípadà ojú-ọjọ́ leè mú oúnjẹ hán, kò ní sí oúnjẹ ní ọ̀pọ̀ yanturu àti pé yóò dín iṣẹ́ ìṣaralóore tí oúnjẹ máa ń ṣe kù. Bí àpẹẹrẹ, àpọ̀jù ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru, àyípadà ìrọ̀jò, àìtó omi leè fa àìso dáadáa irúgbìn tí yóò fàbọ̀ sára irè.

Oúnjẹ Àgbáyé

Àlékún ooru tàbí òtútù lè fa ìdíwọ́ fún oúnjẹ láti dé ibi tí a ti nílòo rẹ̀, àti pé ọ̀hán gógó oúnjẹ yóò pọ̀ síi lọ́jọ́ iwájú. Àpọ̀jù ipa àyípadà ojú-ọjọ́ yóò mú kí oúnjẹ ó tètè díbàjẹ́. Àpọ̀jù ooru máa pa àwọn ẹranko lára ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Láti ìgbàdégbà, ó ṣe é ṣe kí àpọ̀jù ooru ó mú kí àrùn ó fọ́nká bí òkòo àkàntàpó, fa àìrọ́mọbí, àti mú kí ìfúnwàrà ó má pọ̀.

Ọ̀gbẹlẹ̀ kò ní mú kí ìjẹ ẹran-ọ̀sìn ó sùwábọ̀. Ó máa ń dín papa oko oúnjẹ ẹran-ọ̀sìn kù. Ọ̀dá agbègbè mìíràn lè pẹ́ fún ìgbà pípẹ́ látàrí òjò tí kò rọ̀. Fún àwọn ẹranko tí ó ń jẹ àgbàdo, àyípadà sí irúgbìn látàrí ọ̀dá lè fa ìṣòro rẹbutu.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Yàtọ̀ sí wí pé àyípadà ojú-ọjọ́ yóò mú oúnjẹ hán, ipa wo ni yóò tún ní fún ìpèsè oúnjẹ?
 • Àwọn ẹ̀dá inú omi àti ìdínkù ẹja

Àwọn ẹ̀dá inú omi, tàbí ti ọ̀sà tàbí ti òkun, ni àwọn ewéko, ẹranko àti àwọn ẹ̀dá gbogbo tí ó fi omi iyọ̀ òkun tàbí ọ̀sà ṣe ibùgbé, tàbí àwọn irúfẹ́ odò. Ní pàtàkì, àwọn ẹ̀dá inú omi ní ipa tí ó ń kó nínú ìmúró iléayé. Àwọn ẹ̀dá inú omi máa ń pèsè òyì-iná àti irúfẹ́ òyìkan báyìí. Bí ẹ̀bádò ṣe rí kò sẹ́yìn-in àwọn ẹ̀dá inú omi, kódà àwọn ẹ̀dá àìfojúrí inú omi máa ń ṣe ìrànwọ́ ní ti ìṣẹ̀dá ilẹ̀ tuntun.

Ẹja Ń Tán Lọ

Onírúurú àrùn omi ni ó ti ṣẹ́yọ tí ó sì jẹ́ wí pé ojú-ọjọ́ tí ó ń yí ìwàa rẹ̀ padà sí ọ̀tun ni sábàbí. Àpọ̀jù ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru omi tòun ìpele omi àgbáyé ni ó ti mú kí àrùn àfòmọ́ ìsán ó gba omi kan títí dé bèbè omi Atlantic. Ìlọ́wọ́ọ́rọ́ ìgbà òtútù ni Arctic ni ó ń lọ́wọ́ sí àrùn irúfẹ́ ẹja kan tí a pè ní salmon ní Ọ̀sà Bering látàrí àìpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́ ẹja Yukon Chinook Salmon. Ní ìparí, ooru ti fa àjàkálẹ̀ àrùn tí ó kó bá iyùn, koríkoomi, àti irúfẹ́ ìgbín omi kan tí à ń pè ní abalone ní èdèe Gẹ̀ẹ́sì. Àyípadà ojú-ọjọ́ yóò padà wá mú kí àwọn ọ̀kẹ̀ àìmọye ẹja ọlọ́kanòjọ̀kan inú ibú omi ó di ohun àtijọ́ nítorí pé ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àwọn àkàndá ẹja wọ̀nyí ò pọ̀ mọ́.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Báwo ni ìlọ́wọ́ọ́rọ́ omi òkun àti ọ̀sà ṣe ń dá ẹ̀mí ẹranko omi légbodò?
 2. Ọ̀nà wo ni àrùn omi ń gbà ṣẹ́yọ?
 • Ìlọ́wọ́ọ́rọ̀ Ilé-ayé

Ìgbóná ilé ayé tàbí ìlọ́wọ́ọ́rọ̀ ilé-ayé ni ìwọ̀n-òtútù-tàbí-ooru orílẹ̀ alààyè, ibú omi àti àyíká tí ó ń ròkè ju bí ó ti ṣe yẹ lọ.
Ní nǹkan bí 50 ọdún sẹ́yìn, àkópọ̀ agbede ooru àgbáńláayé ti rékọjá ààlà ju bí ó ti ṣe wà ní àkọsílẹ̀. Àwọn onímọ̀ sì ti ṣá wa ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ wí pé ó ń peléke síwájú sí i ni. Ẹ̀wẹ̀wẹ̀ àwọn kan ní kò sí ohun tí ó jọ ọ́, wí pé ìwọ̀n ooru àgbáyé ti dúró “gbọin” sí ojú kan, ó dẹ̀ ti “lọ́ra”, àmọ́ ṣá o, ìwádìí èyí-ò-jọ̀yìí tí a tẹ̀ jade sínú ìwé ìròyìn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ta àwọn èrò bẹ́ẹ̀ nù.

Ìlọ́wọ́ọ́rọ̀ Ilé-ayé

Àpọ̀jù èéfín àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ẹ rẹ̀ tí ó ń ba afẹ́fẹ́ àyíká jẹ́ tí ó ń gba agbára ìtànṣán oòrùn tí ó yẹ kí ó jade kúrò nínú àgbáńlá ayé sí ará. Ohun tí ó yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ ni pé ó yẹ kí àwọn ooru ìtànṣán oòrùn yìí ó jade lọ sí ìta àgbáńláayé ni àmọ́ àwọn tí ó ti sá sínú afẹ́fẹ́ àyíká wọ̀nyí tí ó lè wà bẹ́ẹ̀ fún ọgọ́rùn-ún ọdún kò jẹ́, kaka kí ooru ó jade níṣe ni ó ń padà sínú ayé, tí ó ń mú kí ooru ó lékún síi, èyí gan-an ni eku ẹdá tí ó ń dá àyípadà ojú-ọjọ́ sílẹ̀. Onímọ̀ tí kì í ní ìlọ̀ wí pé àwọn àyípadà oníṣísẹ̀ntẹ̀lé yìí ní ń fa ìjì líle, ọ̀dá àti òjò àrọ̀ìrọ̀dá tí ẹnìkan kò rí irúu rẹ̀ rí.

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Báwo ni ìgbóná ilé ayé ṣe bẹ̀rẹ̀?
 2. Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ara àyípadà ojú-ọjọ́ jáde?

Èròǹgbà tuntun

Ìṣàmúbádọ́gba àyípadà ojú-ọjọ́ ni ọ̀nà tí yóò mú nǹkan rọrùn fún ìṣòro ìgbóná àgbáyé (tí a tún mọ̀ sí“àyípadà ojú-ọjọ́” tàbí “àyípadà ojú-ọjọ́ tí ó t’ara ìbàjẹ́ àyíká ọwọ́ ọmọ-ènìyàn ṣẹ́yọ”). Ìgbìmọ̀ Ìjọba àjọṣepọ̀ lórí Àyípadà Ojú-ọjọ́ (IPCC) sọ pé ìsámúbádọ́gba ni: ‘ìlànà ìṣèbámú pẹ̀lú afẹ́fẹ́ ilẹ̀ bí ó ṣe wà tàbí èyíkéyìí àyípadà tí ó bá dé bá a àti arapa rẹ̀. Ní àwọn ètò ìgbé ayé ẹ̀dá-ọmọènìyàn, ìmọ́lára máa ń dín tàbí gbégidínà ewu tàbí ṣe àmúlò àwọn àǹfààní tí ó wà. Ní àwọn ètò àdánidá mìíràn, ìdásí ọmọ-ènìyàn lè mú àwọn àtúntò sí ìgbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú àyípadà ojú-ọjọ́ àti ipa rẹ̀’.

Èròǹgbà tuntun

Àtúntò yìí yóò bá ohun amáyé dẹrùn, iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ètò ẹ̀kọ́. Kódà bí ìtujáde èéfín dà sínú àyíká bá ṣẹ́pẹ́rẹ́ mọ́wọ́ wálẹ̀ láìpẹ́, ìgbóná àgbáńláayé àti ipa rẹ̀ yóò máa bẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún látàrí ìgbà ìdádúró ìgbóná àgbáńláayé tí ó ti kọjá, àti pé ìsàmùdọ́gba nìkan ni ó dájú jùlọ láti kojú àyípadà ojú-ọjọ́.


Ìṣèbámu pẹ̀lú àyípadà ojú-ọjọ́ yàtọ̀ láti agbègbè kan sí agbègbè mìíràn, ó dá lé bí ipa náà bá ṣe bá àyíká. Ìsàmùdọ́gba pẹ̀lú àyípadà ojú-ọjọ́ pọn dandan ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde nítorí wí pé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyẹn ni ipa àyípadà ojú-ọjọ́ ti ń jà jù. Ìṣèbámu pẹ̀lú àyípadà yìí kò dọ́gba láti agbègbè kan dé agbègbè mìíràn, àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde kò fi bẹ́ẹ̀ ní tó láti kojú àyípadà. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà àtúntò tí ó gbọdọ̀ wáyé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣèbámu pẹ̀lú afẹ́fẹ́ ilẹ̀ ni:
• Lílo àwọn ohun-èlò tí yóò mú ìṣàn agbára ṣẹ́pẹ́rẹ́
• Gbíngbin igi tí ó lè gba ooru sára dáadáa
• Pípọn omi òjò sílẹ̀ sínú kùdù, abẹ́ ilẹ̀ àti lílo omi òjò nínú ilé
• Ìkéde nípa àyípadà ojú-ọjọ́
• Lílo ẹ̀rọ apèsè iná mànàmáná láti ara oòrùn àti atẹ́gùn
• Lílo òrùlé agbagbára oòrùn sílẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí oorú pọ̀ nínú ilé

Ìbéèrè ohun tí o kà

 1. Báwo ni a ṣe lè dẹ́kun ìṣòro àyípadà ojú-ọjọ́?

Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè

Tẹ àwòrán ìsàlẹ̀ yìí kí o yẹ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè ohun tí o kà lókè wò.

Creative Commons License

Iṣẹ́ yìí wà lábẹ́ àṣẹ Creative Commons Attribution-ShareAlike 4.0 International License.

There are no comments yet

Why not be the first

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *