Alternating Current (AC)

Ìṣàn Àtagbà (AC)

 

Ìṣàn àtagbà (AC) ni irúfẹ́ ìṣàn iná mànàmáná tí ó máa ń fì síwá sẹ́yìn nídàágbá kọ̀ọ̀kan, ní èyí tí ó fi yàtọ̀ sí ìṣàn tààrà (DC) tí ó máa ń ṣàn sí ìhà kan ṣoṣo. Ìṣàn àtagbà ni ẹ̀rọ amúnáwá tàbí ẹ̀rọ ayíbírí afi-omi-múnáwá ń lò, bákan náà ni ihò ara ògiri alágbára iná inú ilée wá. Púpọ̀ nínú àwọn ohun èlò alonáa mànàmáná bí iná-amọ́roro, ẹ̀rọ-afátẹ́gùn, ẹ̀rọ-amohùnmáwòrán, ẹ̀rọ-amúlétutù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní í lo ìṣàn àtagbà fún gbígba agbára iná.

Alternating current (AC) is an electric current which periodically reverses direction, in contrast to direct current (DC) which flows only in one direction. Current produced by generators or Turbine are AC currents and the current we get from our home power sockets are AC current. Mostly Electrical appliances like bulb, fan, television, air conditioner and so on and so forth are works on AC current.