8
May
Off
Òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) Òye tí kì í ṣe ti ẹ̀dá [ọmọ ènìyàn] Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) jẹ́ ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ ayárabíàṣá tí ó ń ṣe ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀rọ oní-òye, tí ó ń ronú àti ṣiṣẹ́ bí ẹ̀dá ọmọ-ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ ìdáfọ̀mọ̀, wíwà ojútùú síṣòro, tòun ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ìṣètò nǹkan. Òye Tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá náà ló ṣe atọ́nà Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́. Artificial Intelligence (AI) is the branch of...
22
Mar
Off
Àfọ́ di kíkọ sílẹ̀ Noun Bí kò sí Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́, kò sí àfọ́-di-kíkọ-sílẹ̀. Àpèkọ ni ìmọ̀ ọgbọ́n-àmúṣe arannilọ́wọ́ fún ẹni tí kíkọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ṣòro fún. Àpèkọ náà ni à ń pè ní "àfọ́ di kíkọ-sílẹ̀," "ohùn di ọ̀rọ̀ kíkọ sílẹ̀" tàbí "ìdáfọ̀mọ̀". If there is no Machine Learning, there is no Speech-to-Text. Dictation is an assistive technology tool that can help with writing issues. Dictation...
22
Mar
Off
Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn Noun Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn ni yó ka ohun t'ó wà lójú-ẹ̀rọ l’óhùn. Ọ̀rọ̀ọ́ di ohùn ni ọgbọ́n-àmúṣe àfọ̀ tí ó ń yí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ di ohùn. Nítorí àwọn tí kò ríran ni a fi pèsè ohùn àfọ̀ ti ẹ̀rọ tí yó "ka" ọ̀rọ̀ sẹ́tígbọ̀ọ́ òǹṣàmúlò. It is Text-to-speech that reads what is on the screen using voice. Text to speech (TTS), is...