22
Mar
Off
Okùn Noun Nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, okùn ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ààmì/ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣiṣẹ́ kan. In computer programming, a string is a sequence of characters for a certain purpose.
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká Noun Òṣùwọ̀n-ọ̀rìnrìn-àyíká ni ohun èlò tí a fi ń wọn ọ̀rìnrìn àyíká, tí a fi ń ṣe ìwòye ojú-ọjọ́ àti gíga. Baros tí ó túmọ̀ sí “ìwúwo” + meter "ìwọ̀n/òṣùwọ̀n" = Ẹ̀rọ òṣùwọ̀n èéfún afẹ́fẹ́ ojú-ọjọ́. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ Robert Boyle ló hu ìmọ̀ èdè-ìperí náà (1627-1691). Ọdún 1643 ni ọmọ ilẹ̀ Italy Evangelista Torricelli tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀dá-àrígbéwọ̀n hùmọ̀ ohun-èlò náà tí wọ́n kọ́kọ́...
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná Noun Òṣùwọ̀n-iná-mànàmáná ni irúfẹ́ ẹ̀rọ kan t’ó ń wọn iye iná tí ilé, iléeṣẹ́, tàbí ẹ̀rọ aloná ń lò. An electricity meter or energy meter is a device that measures the amount of electric energy consumed by a residence, business, or an electrically powered device.  
22
Mar
Off
Iṣẹ́-àrídìmú Noun Pàrọ̀ Iṣẹ́-àrídìmú ẹ̀rọ-ayàwòrán. Change the camera Hardware.
22
Mar
Off
Iṣẹ́-àìrídìmú Noun Fi iṣẹ́-àìrídìmú fún àwòrán yíyà sí orí ẹ̀rọ. Install graphic design Software on the system.
22
Mar
Off
Àfọ́ di kíkọ sílẹ̀ Noun Bí kò sí Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́, kò sí àfọ́-di-kíkọ-sílẹ̀. Àpèkọ ni ìmọ̀ ọgbọ́n-àmúṣe arannilọ́wọ́ fún ẹni tí kíkọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ṣòro fún. Àpèkọ náà ni à ń pè ní "àfọ́ di kíkọ-sílẹ̀," "ohùn di ọ̀rọ̀ kíkọ sílẹ̀" tàbí "ìdáfọ̀mọ̀". If there is no Machine Learning, there is no Speech-to-Text. Dictation is an assistive technology tool that can help with writing issues. Dictation...
22
Mar
Off
Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn Noun Ọ̀rọ̀ọ́-di-ohùn ni yó ka ohun t'ó wà lójú-ẹ̀rọ l’óhùn. Ọ̀rọ̀ọ́ di ohùn ni ọgbọ́n-àmúṣe àfọ̀ tí ó ń yí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ di ohùn. Nítorí àwọn tí kò ríran ni a fi pèsè ohùn àfọ̀ ti ẹ̀rọ tí yó "ka" ọ̀rọ̀ sẹ́tígbọ̀ọ́ òǹṣàmúlò. It is Text-to-speech that reads what is on the screen using voice. Text to speech (TTS), is...