27
Mar
Off
Sanwósí Verb San + owó + sí Sanwósí orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ. Subscribe on your mobile phone. Fi + ọwọ́ + sí Fọwọ́sí  ìgbàròyìn tuntun Subscribe to get the latest news
27
Mar
Off
Owóòlò-ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká Noun Owó + ìlò + ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká Owóòlò-ayélujára orí ẹ̀rọ-alágbèéká ni àwọn àkópọ̀ ohun orí ayélujára tí a gbé sórí ẹ̀rọ bí i ẹ̀rọ-alágbèéká àti ẹ̀rọ-ọlọ́pọ́n tí ó la orí ìsopọ̀ àìlokùn ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́.  Mobile data is Internet content delivered to mobile devices such as smartphones and tablets over a wireless cellular connection. 
27
Mar
Off
Ìsanwósí Noun Ìsan + owó + sí (to pay to have access to something) Mo ṣe ìsanwósí DSTV. I did a DSTV subscription.  Ìfi + orúkọ + sílẹ̀ (to put down one's name/register for a purpose; for access to something) Jẹ́ kí a lọ ṣe ìforúkọsílẹ̀ fún owó-ìlò-ayélujára Let us go for subscription for internet data.
27
Mar
Off
Fifún Verb Fi + fún (give out) Nígbà tí Ọpẹ́yẹmí kọ orúkọ sílẹ̀ tán, ó ṣíra tẹ fifun. After Ọpẹ́yẹmí has entered her name/subscribed, she clicked on submit. Fi ìbéèrè fún Google. Submit a query to Google.
27
Mar
Off
Ipò Noun Èyí ni atọ́ka sí ipò tí ẹ̀rọ tàbí ònṣàmúlò wà, fún àpẹẹrẹ; ipò ìjáde; ipò àìṣedéédé ẹ̀rọ... This is a pointer to the state (condition) of a device or user, for example; exit status, device malfunctioning status...  
27
Mar
Off
Ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ Verb Ìrí-àyè-wọ-ẹ̀rọ-fi-iṣẹ́-ìjẹ́-ránṣẹ́ Èdè ìperí ìráàyèwẹ̀rọfiṣẹ́ẹ̀jẹ́ránṣẹ́ ni dídíbọ́n tàbí títakóró wọ inú ẹ̀rọ, inú iṣẹ́ àìrídìmú, awo àrídìmú tàbí ẹ̀rọ ayárabíàṣá ẹlòmìíràn.  The term spoof refers to hacking or deception that imitates another person, software program, hardware device, or computer.   
22
Mar
Off
Ìránsíwájú Ímeèlì Noun Ìránsíwájú Ímeèlì ni iṣẹ́ fífi iṣẹ́-ìjẹ́ tí a gbà sínú ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára kan ránṣẹ́ sí ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára ẹlòmíràn tàbí àwọn ojúlé àpò-ìwé orí ayélujára mìíràn síwájú sí i.  Email forwarding refers to the operation of re-sending an email message delivered to one email address to one or more different email addresses.
22
Mar
Off
Òǹṣàmúlò Noun Òǹṣàmúlò ni ẹni tí ó ń ṣe àmúlò ẹ̀rọ ayárabíàṣá tàbí iṣẹ́ orí ìsopọ̀. Òǹṣàmúlò sábà máa ń ní ìṣàmúlò tí ẹ̀rọ máa ń dá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i orúkọ-òǹṣàmúlò (tàbí orúkọ òǹṣàmúlò). A user is a person who utilizes a computer or network service. A user often has a user account and is identified to the system by a username (or user name). Other terms for username include login name, screenname (or screen name), account name, nickname (or nick) and handle, 
22
Mar
Off
Òṣùwọ̀n ìgbóná Noun Òṣùwọ̀n-ìgbóná ni ohun èlò tí a fi ń yẹ ìwọ̀n òtútù àti ìgbóná nǹkan wò láti mọ bí nǹkan náà ṣe tutù tàbí gbóná sí. A thermometer is an instrument for measuring or showing temperature (how hot or cold something is).