22
Mar
Off
Ìdáfọ̀mọ̀ Noun Ìdá-ìfọ̀-mọ̀ Àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó bí Ìdá-ìfọ̀-mọ̀, Ọ̀rọ̀-di-ohùn àti Ohùn-di-ọ̀rọ̀-kíkọ-sílẹ̀. Machine learning feature gave birth to Speech Recognition, Text-to-Speech and Speech-to-text.
22
Mar
Off
Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ Noun Kíkọ́ ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ l'ó mú kí ìṣèṣàtúnkọ-ẹ̀rọ àti àsọtẹ́lẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ ó ṣe é ṣe. Kíkọ́ ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ètò òye tí-kìí-ṣe-ti-ẹ̀dá (AI) tí ó ń fi àyè gba ẹ̀rọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ kún ẹ̀kọ́ fún ara rẹ̀ látàrí ìrírí láì ṣe wí pé allows ènìyàn fi ìmọ̀ bọ́ ọ. Pẹ̀lú àbùdá Kíkọ́ Ẹ̀rọ-lẹ́kọ̀ọ́ àwọn iṣẹ́ àìrídìmú leè ṣá ọ̀rọ̀ ìwífún alálàyé jọ fún...
22
Mar
Off
Pátákó-ìtẹ̀wé Noun Pátákó-ìtẹ̀wé èdè Yorùbá ni mo fi máa ń tẹ gbólóhùn lórí ẹ̀rọ. I usually type words on computer with the Yorùbá keyboard.
22
Mar
Off
Ẹ̀rọ-ìdíwọ̀n ìgbóná àti ìtútù Noun Ẹ̀rọ tí ó máa ń fi ìdiwọ̀n ìgbóná àti òtútù Ẹ̀rọ tí ó máa ń ṣe ìwọ̀ntúnwọ̀nsì sí ìgbóná tàbí ìtutù, ó sì tún máa ń mú ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ bí ìgbóná/ìtutù bá dé ìwọ̀n kan.  A device that automatically regulates temperature, or that activates a device when the temperature reaches a certain point.
22
Mar
Off
Ìwífún-alálàyé Noun Ìwífún-alálàyé orí ẹ̀rọ ni àwọn ìwífún tí ó la orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá kọja tí ó jẹ́ kíkó pamọ́ sí orí ẹ̀rọ. Data is information stored and transmissible on computer. Ìwífún-alálàyé-nípa ẹni Personal Data
21
Mar
Off
Òkúta-agbanására Noun (Òkúta agba + iná + sára) Òkúta-agbanására ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ mi ti wú. My phone's battery has swollen.
21
Mar
Off
Ihò-ìtẹ̀bọ̀ Noun Ti okùn afagbárainásẹ́rọ ìbánisọ̀rọ̀ bọ ihò-ìtẹ̀bọ̀ (sọ́kẹ́ẹ̀tì) Insert the phone charger into the socket Ihò-ìtẹ̀bọ̀ gbiná The socket exploded
21
Mar
Off
Afagbárainásẹ́rọ Noun (A+fi+agbára+iná+sí+ẹ̀rọ) Fi afagbárainásẹ́rọ mi gbéná sínú òkúta-agbanására ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká rẹ Use my charger to charge the battery of your mobile phone
21
Mar
Off
Pátákó-gbọọrọ-iṣẹ́ Noun Ìsàlẹ̀ ojú-ẹ̀rọ niPátákó-gbọọrọ-iṣẹ́náà máa ń wà tí ó ní Bẹ̀rẹ̀, àwọn ààmì Pátákó-gbọọrọ-iṣẹ́,... The Taskbar is at the bottom of the desktop and contains the Start, Taskbar icons,...