Awo Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Awo Ẹ̀rọ ìmọ̀ iṣẹ́ tàbí ohun tí a hùmọ̀ọ rẹ̀ fún ìdí kan pàtó; tí ó ń ṣe iṣẹ́ kan pàtó. Bí àpẹẹrẹ, ọgbọ́n, ìlànà-iṣẹ́, ète àti/tàbí ẹ̀rọ gẹ́gẹ́ bíi pátákó-ìtẹ̀wé, ẹ̀rọ gbohùngbohùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A machine or an object that has been invented for a particular purpose; that does a special job. For example, initiative, procedure, and/or a machine...
Awòhuntójúòlèrí Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Awò + ohun + tí + ojú + lásán + kò + lè + rí Awòhuntójúòlèrí ni ohun èlò inú ilé àyẹ̀wò tí a fi ń ṣe ìwádìí àwọn ohun tí ó jógán gan-an tí ojú lásán kò leè rí. A microscope is a laboratory instrument used to examine objects that are too small to be seen by the naked eye. [caption...
Awòhunjínjìn Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Awò + ohun + jínjìn Awo tí a fi ń sọ nǹkan tí ó wà ní ọ̀nà jínjìn réré di nílá. Ó máa ń mú kí àyẹ̀wò sí àwọn ẹ̀dá ti ọ̀run àti àwọn nǹkan mìíràn nínú Èdùmàrè rọrùn. A device used to magnify object from far distance. It makes analysis of the celestial bodies and universe easy. [caption id="attachment_2407" align="aligncenter" width="300"]...
Ẹ̀rọ-agbẹ̀dàwòrán Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ẹ̀rọ-agbẹ̀dàwòrán máa ń yí àwòrán padà sí ẹ̀dà àìrídìmú fún lílò lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá. . Scanner converts images into digital versions for use on a computer.
Ìfẹ̀rọ ayárabíàṣá gbéṣẹ́ àìrídìmú sórí àwọsánmà Láyé òde òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti iléeṣẹ́ ni ó ń lo ìlànà ìfẹ̀rọ ayárabíàṣá gbéṣẹ́ àìrídìmú sórí àwọsánmà pa iṣẹ́ wọn mọ́. In today's world, many people and companies are using the e-cloud process to store their works.
Àká iṣẹ́ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Àká iṣẹ́ ni ibi ìpamọ́ ohun gbogbo tí à ń ṣe ní orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá. The hard disk is the store house of all activities that we perform on the computer.
Ìṣàsopọ̀ tinú Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ìṣàsopọ̀ ti + inú Èyí ni ìṣàsopọ̀ tinú tàbí ìṣàsopọ̀ ti agbègbè kan ṣoṣo tí ó wà fún àwọn ènìyàn kan ṣoṣo. Ìyẹn ìṣàsopọ̀ abẹ́lẹ̀ tí ó jẹ́ wípé àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó ní àyè sí ìlò rẹ̀. This is Intra-network or local area network for just one entity. That is a private network that only a few people has...
Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá Àgbélétantẹ̀ Ọ̀rọ̀-orúkọ (Noun) Ẹ̀rọ a + yára + bí + àṣá À + gbé + lé + itan + tẹ̀ Pa ojú ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àgbélétantẹ̀ yẹn dé kí o wá. Close that laptop (computer) and come.